1. Àwọn wolii ati àwọn olùkọ́ wà ninu ìjọ tí ó wà ní Antioku. Ninu wọn ni Banaba ati Simeoni tí wọn ń pè ní Adúláwọ̀ wà, ati Lukiusi ará Kirene, ati Manaeni tí wọ́n jọ tọ́ dàgbà pẹlu Hẹrọdu baálẹ̀, ati Saulu.
2. Bí wọ́n ti jọ ń sin Oluwa, tí wọ́n ń gbààwẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ sọ fún wọn pé, “Ẹ ya Banaba ati Saulu sọ́tọ̀ fún mi, fún iṣẹ́ pataki kan tí mo ti pè wọ́n fún.”