3. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí pẹlu wa. Nígbà tí a jẹ́ ọmọde, a jẹ́ ẹrú àwọn oríṣìíríṣìí ẹ̀mí tí a kò fojú rí.
4. Ṣugbọn nígbà tí ó tó àkókò tí ó wọ̀, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ wá. Obinrin ni ó bí i, ó bí i lábẹ́ òfin àwọn Juu,
5. kí ó lè ra àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin pada, kí á lè sọ wá di ọmọ.
6. Ọlọrun rán ẹ̀mí ọmọ rẹ̀ sinu ọkàn wa, Ẹ̀mí yìí ń ké pé, “Baba!” láti fihàn pé ọmọ ni ẹ jẹ́.
7. Nítorí náà, ẹ kì í ṣe ẹrú mọ́ bíkòṣe ọmọ. Bí ẹ bá wá jẹ́ ọmọ, ẹ di ajogún nípasẹ̀ iṣẹ́ Ọlọrun.
8. Ṣugbọn nígbà tí ẹ kò mọ Ọlọrun, ẹ di ẹrú àwọn ẹ̀dá tí kì í ṣe Ọlọrun.
9. Nisinsinyii ẹ mọ Ọlọrun, tabi kí á kúkú wí pé Ọlọrun mọ̀ yín. Báwo ni ẹ ṣe tún fẹ́ yipada sí àwọn ẹ̀mí tí a kò fi ojú rí, tí wọ́n jẹ́ aláìlera ati aláìní, tí ẹ tún fẹ́ máa lọ ṣe ẹrú wọn?
10. Ẹ̀ ń ya oríṣìíríṣìí ọjọ́ sọ́tọ̀, ẹ̀ ń ranti oṣù titun, àkókò ati àjọ̀dún!
11. Ẹ̀rù yín ń bà mí pé kí gbogbo làálàá mi lórí yín má wá jẹ́ lásán!
12. Ẹ̀yin ará, mo bẹ̀ yín ni, ẹ dàbí mo ti dà nítorí èmi náà ti dàbí yín. Ẹ kò ṣẹ̀ mí rárá.