7. Nítorí Ọlọrun ni Ọba gbogbo ayé;Ẹ fi gbogbo ohun èlò ìkọrin kọ orin ìyìn!
8. Ọlọrun jọba lórí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè;Ó gúnwà lórí ìtẹ́ mímọ́ rẹ̀.
9. Àwọn ìjòyè orílẹ̀-èdè kó ara wọn jọpẹlu àwọn eniyan Ọlọrun Abrahamu.Ọlọrun ni aláṣẹ gbogbo ayé;òun ni ọlọ́lá jùlọ!