1. N óo máa yin OLUWA ní gbogbo ìgbà;ìyìn rẹ̀ yóo máa wà ní ẹnu mi nígbà gbogbo.
2. OLUWA ni èmi óo máa fi yangàn;kí inú àwọn olùpọ́njú máa dùn nígbà tí wọ́n bá gbọ́.
3. Ẹ bá mi gbé OLUWA ga,ẹ jẹ́ kí á jùmọ̀ gbé orúkọ rẹ̀ lékè!
4. Mo ké pe OLUWA, ó sì dá mi lóhùn,ó sì gbà mí lọ́wọ́ gbogbo ohun tí ń bà mí lẹ́rù.