1. Kí ló dé tí o fi jìnnà réré, OLUWA,tí o sì fara pamọ́ ní ìgbà ìpọ́njú?
2. Pẹlu ìgbéraga ni eniyan burúkú fi ń dọdẹ àwọn aláìní;jẹ́ kí ó bọ́ sinu tàkúté tí ó fi àrékérekè dẹ.
3. Eniyan burúkú ń fọ́nnu lórí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀,Ó ń bu ọlá fún wọ̀bìà, ó sì ń kẹ́gàn OLUWA.
4. Eniyan burúkú kò wá Ọlọrun, nítorí ìgbéraga ọkàn rẹ̀,kò tilẹ̀ sí ààyè fún Ọlọrun ninu gbogbo ìrònú rẹ̀.
5. Nígbà gbogbo ni nǹkan ń dára fún un.Ìdájọ́ rẹ, Ọlọrun, ga pupọ, ó ju òye rẹ̀ lọ;ó ń yọ ṣùtì ètè sí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀.
6. Ó ń rò lọ́kàn ara rẹ̀ pé, kò sí ohun tí ó lè bi òun ṣubú,ati pé ní gbogbo ọjọ́ ayé òun, òun kò ní ní ìṣòro.
7. Ẹnu rẹ̀ kún fún èpè, ẹ̀tàn ati ìhàlẹ̀;ìjàngbọ̀n ati ọ̀rọ̀ ibi sì wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀.
8. Ó ń lúgọ káàkiri létí abúlé,níbi tó fara pamọ́ sí ni ó ti ń pa àwọn aláìṣẹ̀;ó ń fojú ṣọ́ àwọn aláìṣẹ̀ tí yóo pa.
9. Ó fara pamọ́ bíi kinniun tí ó wà ní ibùba;ó fara pamọ́ láti ki aláìní mọ́lẹ̀;ó mú aláìní, ó sì fi àwọ̀n fà á lọ.
10. Ó wó aláìṣẹ̀ mọ́lẹ̀, ó tẹ orí wọn ba,ó sì fi agbára bì wọ́n ṣubú.
11. Ó sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé, “Ọlọrun ti gbàgbé,OLUWA ti gbé ojú kúrò, kò sì ní rí i laelae.”
12. Dìde, OLUWA; Ọlọrun, wá nǹkankan ṣe sí i;má sì gbàgbé àwọn tí a nilára.
13. Kí ló dé tí eniyan burúkú fi ń kẹ́gàn Ọlọrun,tí ó ń sọ lọ́kàn rẹ̀ pé, “Ọlọrun kò ní bi mí?”
14. Ṣugbọn ìwọ Ọlọrun rí gbogbo nǹkan,nítòótọ́, o kíyèsí ìṣòro ati ìyà,kí o baà lè fi ọwọ́ ara rẹ gbẹ̀san;nítorí ìwọ ni àwọn aláìṣẹ̀ gbẹ́kẹ̀lé,ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìníbaba.
15. Ṣẹ́ eniyan burúkú ati aṣebi lápá,tú àṣírí gbogbo ìwà burúkú rẹ̀,má sì jẹ́ kí ọ̀kan ninu wọn farasin.