Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú ọrẹ yín wá fún OLUWA ninu ìdámẹ́wàá tí àwọn ọmọ Israẹli bá san fun yín. Ẹ óo mú ọrẹ tí ó jẹ́ ti OLUWA wá fún Aaroni alufaa.