38. Àwọn ọmọ Senaa jẹ́ ẹgbaaji ó dín aadọrin (3,930).
39. Àwọn alufaa nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Jedaaya, tí wọ́n jẹ́ ti ìdílé Jeṣua, jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé mẹtalelaadọrin (973).
40. Àwọn ọmọ Imeri jẹ́ ẹgbẹrun ó lé mejilelaadọta (1,052).
41. Àwọn ọmọ Paṣuri jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹtadinlaadọta (1,247).
42. Àwọn ọmọ Harimu jẹ́ ẹgbẹrun ó lé mẹtadinlogun (1,017).
43. Àwọn ọmọ Lefi nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Jeṣua, tí wọn ń jẹ́ Kadimieli, ní ìdílé Hodefa, jẹ́ mẹrinlelaadọrin.
44. Àwọn akọrin nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Asafu jẹ́ mejidinlaadọjọ (148).
45. Àwọn olùṣọ́ ẹnubodè nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Ṣalumu, àwọn ọmọ Ateri, àwọn ọmọ Talimoni, àwọn ọmọ Akubu, àwọn ọmọ Hatita, ati àwọn ọmọ Ṣobai. Gbogbo wọn jẹ́ mejidinlogoje (138).
46. Àwọn iranṣẹ tẹmpili nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Siha, àwọn ọmọ Hasufa, ati àwọn ọmọ Tabaoti,