OLUWA àwọn ọmọ ogun ní:“Wò ó! Mo ti gbógun tì ọ́, Ninefe,n óo ká aṣọ kúrò lára rẹ, n óo fi bò ọ́ lójú;n óo tú ọ sí ìhòòhò lójú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.Àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn yóo rí ìhòòhò rẹojú yóo sì tì ọ́.