9. O óo lágbára ju àwọn ọ̀tá rẹ lọ, a óo sì pa wọ́n run.
10. Ní ọjọ́ náà, n óo pa àwọn ẹṣin yín run, n óo sì run gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun yín.
11. N óo pa àwọn ìlú tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ yín run, n óo sì wó ibi ààbò yín lulẹ̀.
12. N óo pa àwọn oṣó run ní ilẹ̀ yín, ẹ kò sì ní ní aláfọ̀ṣẹ kankan mọ́.
13. N óo run àwọn ère ati àwọn òpó oriṣa yín, ẹ kò sì ní máa bọ iṣẹ́ ọwọ́ yín mọ́.
14. N óo run àwọn ère oriṣa Aṣera láàrin yín, n óo sì run àwọn ìlú yín.
15. Ninu ibinu ati ìrúnú mi, n óo gbẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò pa àṣẹ mi mọ́.