9. Àkọsílẹ̀ ìran wọn ní ìdílé, àwọn baálé baálé ní ilé baba wọn, tí wọ́n jẹ́ akọni jagunjagun, gbogbo wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati igba (20,200).
10. Jediaeli ni baba Bilihani; Bilihani bí ọmọ meje: Jeuṣi, Bẹnjamini, Ehudu, Kenaana, Setani, Taṣiṣi ati Ahiṣahari.
11. Gbogbo wọn jẹ́ ọmọ Jediaeli; àwọn tí wọ́n jẹ́ baálé baálé ní ilé baba wọn ati akọni jagunjagun ninu ìran wọn tó ẹẹdẹgbaasan-an ó lé igba (17,200).
12. Ṣupimu ati Hupimu jẹ́ ọmọ Iri, ọmọ Aheri sì ni Huṣimu.
13. Nafutali bí ọmọ mẹrin: Jasieli, Guni, Jeseri, ati Ṣalumu. Biliha ni ìyá baba wọn.
14. Manase fẹ́ obinrin kan, ará Aramea; ọmọ meji ni obinrin náà bí fún un; Asirieli, ati Makiri, baba Gileadi.
15. Makiri fẹ́ iyawo kan ará Hupi, ati ọ̀kan ará Ṣupimu. Orúkọ arabinrin rẹ̀ ni Maaka. Orúkọ ọmọ rẹ̀ keji ni Selofehadi; tí gbogbo ọmọ tirẹ̀ jẹ́ kìkì obinrin.
16. Maaka, Iyawo Makiri, bí ọmọ meji: Pereṣi ati Ṣereṣi. Ṣereṣi ni ó bí Ulamu ati Rakemu;
17. Ulamu sì bí Bedani. Àwọn ni ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manase.
18. Arabinrin Gileadi kan tí ń jẹ́ Hamoleketu ni ó bí Iṣodu, Abieseri, ati Mahila.
19. Ṣemida bí ọmọkunrin mẹrin: Ahiani, Ṣekemu, Liki, ati Aniamu.
20. Àwọn arọmọdọmọ Efuraimu nìwọ̀nyí: Ṣutela ni baba Beredi, baba Tahati, baba Eleada, baba Tahati,
21. baba Sabadi, baba Ṣutela, Eseri, ati Eleadi; Eseri ati Eleadi yìí ni àwọn ará ìlú Gati pa nígbà tí wọ́n lọ kó ẹran ọ̀sìn àwọn ará Gati.