1. Àwọn ọmọ Juda ni: Peresi, Hesironi, Kami, Huri, ati Ṣobali.
2. Ṣobali ni ó bí Reaaya. Reaaya sì bí Jahati. Jahati ni baba Ahumai ati Lahadi. Àwọn ni ìdílé àwọn tí ń gbé Sora.
3. Àwọn ọmọ Etamu ni: Jesireeli, Iṣima, ati Idibaṣi. Orúkọ arabinrin wọn ni Haseleliponi.
4. Penueli ni baba Gedori. Eseri bí Huṣa. Àwọn ni ọmọ Huri, àkọ́bí Efurata, tí ó jẹ́ baba Bẹtilẹhẹmu.
5. Aṣuri, baba Tekoa, ní aya meji: Hela ati Naara.
6. Naara bí ọmọ mẹrin fún un: Ahusamu, Heferi, Temeni, ati Haahaṣitari.
7. Hela bí ọmọ mẹta fún un: Sereti, Iṣari, ati Etinani.
8. Kosi ni baba Anubi ati Sobeba. Òun ni baba ńlá àwọn ìdílé Ahaheli, ọmọ Harumu.