Ojú tì wọ́n pupọ wọn kò lè pada sílé. Nígbà tí Dafidi gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn, ó ranṣẹ sí wọn pé kí wọ́n dúró sí Jẹriko títí tí irùngbọ̀n wọn yóo fi hù, lẹ́yìn náà kí wọ́n máa pada bọ̀ wá sílé.