Dafidi ṣe akiyesi pé Ọlọrun ti fi ìdí ìjọba òun múlẹ̀ lórí Israẹli, ati pé Ọlọrun ti gbé ìjọba òun ga nítorí àwọn ọmọ Israẹli eniyan rẹ̀.