Saulu ba sọ fún ọdọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀ pé, “Fa idà rẹ yọ, kí o sì gún mi pa, kí àwọn aláìkọlà ará Filistia má baà fi mi ṣẹ̀sín.” Ṣugbọn ẹni tí ń ru ihamọra rẹ̀ kọ̀, nítorí pe ẹ̀rù bà á; nítorí náà, Saulu fa idà ara rẹ̀ yọ, ó sì ṣubú lé e.