Ẹ pe gbogbo eniyan jọ,kí ẹ sì ya ìjọ eniyan sí mímọ́.Ẹ pe àwọn àgbààgbà jọ,ẹ kó àwọn ọmọde ati àwọn ọmọ ọwọ́ jọ.Kí ọkọ iyawo jáde láti inú yàrá rẹ̀,kí iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé náà jáde ninu yàrá rẹ̀.