23. Ǹjẹ́ mo bẹ̀ yín pé kí ẹ gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá;tabi pé kí ẹ rà mí pada kúrò lọ́wọ́ aninilára?
24. “Ó dára, mo gbọ́, ẹ wá kọ́ mi,ẹ ṣàlàyé ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ṣẹ̀ fún mi;n óo sì dákẹ́ n óo tẹ́tí sílẹ̀.
25. Lóòótọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ ní agbára,ṣugbọn kí ni ẹ̀ ń bá mi wí lé lórí.
26. Ẹ rò pé mò ń fi ọ̀rọ̀ ṣòfò lásán ni?Kí ni ẹ̀ ń dásí ọ̀rọ̀ èmi onírora sí?
27. Ẹ tilẹ̀ lè ṣẹ́ gègé lórí ọmọ òrukàn,ẹ sì lè díye lé ọ̀rẹ́ yín.
28. “Ẹ gbọ́, ẹ wò mí dáradára,nítorí n kò ní purọ́ níwájú yín.
29. Mo bẹ̀ yín, ẹ dúró bẹ́ẹ̀,kí ẹ má baà ṣẹ̀.Ẹ dúró bẹ́ẹ̀, nítorí n kò lẹ́bi.
30. Ṣé ẹ rò pé mò ń parọ́ ni?Àbí n kò mọ nǹkan burúkú yàtọ̀?