19. bí mo bá ti rí ẹni tí ó ń kú lọ,nítorí àìrí aṣọ bora,tabi talaka tí kò rí ẹ̀wù wọ̀,
20. kí ó sì súre fún mi,nítorí pé ara rẹ̀ móorupẹlu aṣọ tí a fi irun aguntan mi hun,
21. bí mo bá fi ìyà jẹ aláìníbaba,nítorí pé mo mọ eniyan ní ilé ẹjọ́,
22. jẹ́ kí apá mi já kúrò léjìká mi,kí ó yọ ní oríkèé rẹ̀.
23. Nítorí ẹ̀rù ìpọ́njú láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ń bà mí,nítorí ògo rẹ̀, n kò lè dán irú rẹ̀ wò.
24. “Bí mo bá gbójú lé wúrà,tí mo sì fi ojúlówó wúrà ṣe igbẹkẹle mi,
25. bí mo bá ń yọ̀ nítorí pé mo ní ọrọ̀ pupọ,tabi nítorí pé ọwọ́ mi ti ba ọpọlọpọ ohun ìní.
26. Tí mo bá ti wo oòrùn nígbà tí ó ń ràn,tabi tí mo wo òṣùpá ninu ẹwà rẹ̀:
27. tí ọkàn mi fà sí wọn;tí mo sì tẹ́wọ́ adura sí wọn.
28. Èyí pẹlu yóo jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,tí adájọ́ gbọdọ̀ jẹ mí níyà fún;nítorí yóo jẹ́ aiṣootọ sí Ọlọrun ọ̀run.
29. “Bí mo bá yọ̀ nítorí ìparun ẹni tí ó kórìíra mi,tabi kí inú mi dùn nígbà tí ohun burúkú bá ṣẹlẹ̀ sí i.
30. (N kò fi ẹnu mi ṣẹ̀kí n gbé e ṣépè pé kí ó lè kú);
31. bí àwọn tí wọn ń gbé inú àgọ́ mi kò bá wí pé,‘Ta ló kù tí kò tíì yó?’
32. (Kò sí àlejò tí ń sun ìta gbangba,nítorí ìlẹ̀kùn ilé mi ṣí sílẹ̀ fún àwọn arìnrìnàjò);
33. bí mo bá fi ẹ̀ṣẹ̀ mi pamọ́ fún eniyan,tí mo sì dé àìdára mi mọ́ra,