Nígbà tí ọba Jehoiakimu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ati àwọn ìjòyè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ọba wá ọ̀nà láti pa á. Nígbà tí Uraya gbọ́, ẹ̀rù bà á, ó sì sálọ sí ilẹ̀ Ijipti.