20. Nípa ìmọ̀ rẹ̀ ni ibú fi ń tú omi jáde,tí ìrì fi ń sẹ̀ láti inú ìkùukùu.
21. Ọmọ mi, di ọgbọ́n tí ó yè kooro ati làákàyè mú,má sì ṣe jẹ́ kí wọn bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ,
22. wọ́n yóo jẹ́ ìyè fún ẹ̀mí rẹ,ati ohun ọ̀ṣọ́ ní ọrùn rẹ.
23. Nígbà náà ni o óo máa rìnláìléwu ati láìkọsẹ̀.
24. Bí o bá jókòó, ẹ̀rù kò ní bà ọ́,bí o bá sùn, oorun yóo máa dùn mọ́ ọ.
25. Má bẹ̀rù àjálù òjijì,tabi ìparun àwọn ẹni ibi,nígbà tí ó bá dé bá ọ,
26. nítorí pé, OLUWA ni igbẹkẹle rẹ,kò sì ní jẹ́ kí o ti ẹsẹ̀ bọ tàkúté.