5. Ẹni tí ó bá ń pọ́n aládùúgbò rẹ̀,ń dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ̀.
6. Eniyan burúkú bọ́ sinu àwọ̀n ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,ṣugbọn olódodo lè kọrin, ó sì lè máa yọ̀.
7. Olódodo a máa bìkítà fún ẹ̀tọ́ àwọn talaka,ṣugbọn àwọn eniyan burúkú kò ní òye irú rẹ̀.
8. Àwọn ẹlẹ́gàn a máa dá rúkèrúdò sílẹ̀ láàrin ìlú,ṣugbọn àwọn ọlọ́gbọ́n a máa paná ibinu.
9. Nígbà tí ọlọ́gbọ́n bá pe òmùgọ̀ lẹ́jọ́,ẹ̀rín ni òmùgọ̀ yóo máa fi rín,yóo máa pariwo, kò sì ní dákẹ́.
10. Àwọn apànìyàn kórìíra olóòótọ́ inú,wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa á.
11. Òmùgọ̀ eniyan a máa bínú,ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa mú sùúrù.
12. Bí aláṣẹ bá ń fetí sí irọ́,gbogbo àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ yóo di eniyankeniyan.
13. Ohun tí ó sọ talaka ati aninilára di ọ̀kan náà ni pé,OLUWA ló fún àwọn mejeeji ní ojú láti ríran.
14. Ọba tí ó dájọ́ ẹ̀tọ́ fún talaka,ní a óo fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ títí.
15. Pàṣán ati ìbáwí a máa kọ́ ọmọ lọ́gbọ́n,ọmọ tí a bá fi sílẹ̀ yóo dójúti ìyá rẹ̀.
16. Nígbà tí eniyan burúkú bá wà lórí oyè, ẹ̀ṣẹ̀ a máa pọ̀ síi,ṣugbọn lójú olódodo ni wọn yóo ti ṣubú.
17. Tọ́ ọmọ rẹ, yóo sì fún ọ ní ìsinmi,yóo sì mú inú rẹ dùn.