1. Má ṣe ìlara àwọn ẹni ibi,má sì ṣe bá wọn kẹ́gbẹ́,
2. nítorí ọkàn wọn ń gbèrò ìparun,ẹnu wọn sì ń sọ̀rọ̀ ìkà.
3. Ọgbọ́n ni a fi ń kọ́lé,òye ni a fi ń fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.
4. Pẹlu ìmọ̀ ni eniyan fi í kóoniruuru nǹkan ìní dáradáraolówó iyebíyekún àwọn yàrá rẹ̀