6. Pẹ̀gànpẹ̀gàn a máa wá ọgbọ́n, sibẹ kò ní rí i,ṣugbọn ati ní ìmọ̀ kò ṣòro fún ẹni tí ó ní òye.
7. Yẹra fún òmùgọ̀,nítorí o kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n lẹ́nu rẹ̀.
8. Ohun tí ó jẹ́ ọgbọ́n fún ọlọ́gbọ́nni pé kí ó kíyèsí ọ̀nà ara rẹ̀,ṣugbọn àìmòye àwọn òmùgọ̀ kún fún ìtànjẹ.
9. Àwọn òmùgọ̀ a máa fi ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ṣe àwàdà,ṣugbọn àwọn olódodo a máa rí ojurere.
10. Kálukú ló mọ ìbànújẹ́ ọkàn ara rẹ̀,kò sì sí àjèjì tí ń báni pín ninu ayọ̀.
11. Ìdílé ẹni ibi yóo parun,ṣugbọn ilé olódodo yóo máa gbèrú títí lae.
12. Ọ̀nà kan wà tí ó dàbí ẹni pé ó tọ́ lójú eniyan,ṣugbọn òpin rẹ̀, ikú ni.
13. Eniyan lè máa rẹ́rìn-ín, kí inú rẹ̀ má dùn,ìbànújẹ́ sì le gbẹ̀yìn ayọ̀.
14. Alágàbàgebè yóo jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́,ẹni rere yóo sì jèrè ìwà rere rẹ̀.