1. Ìre tí Mose eniyan Ọlọrun sú fún àwọn ọmọ Israẹli kí ó tó kú nìyí. Ó ní:
2. OLUWA wá láti orí òkè Sinai,ó yọ gẹ́gẹ́ bí oòrùn láti Edomu,ó ràn sórí àwọn eniyan rẹ̀ láti òkè Parani.Ó wá láti ọ̀dọ̀ ẹgbaarun àwọn ẹni mímọ́,ó gbé iná tí ń jò lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀.
3. Ọlọrun fẹ́ràn àwọn eniyan rẹ̀,gbogbo àwọn tí a yà sọ́tọ̀ fún un wà lọ́wọ́ rẹ̀,nítorí náà ni wọ́n ṣe ń tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀,tí wọ́n sì ń gba àṣẹ lọ́dọ̀ rẹ̀,
4. nígbà tí Mose bá fún wa ní òfin,tí ó jẹ́ ohun ìní gbogbo eniyan Israẹli.
5. Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe di ọba ní Jeṣuruni,nígbà tí gbogbo àwọn olórí péjọ,àní, gbogbo àwọn olórí ninu ẹ̀yà Israẹli.