Ní gbogbo àkókò Solomoni, gbogbo àwọn ọmọ Juda ati àwọn ọmọ Israẹli wà ní alaafia láti ìlú Dani títí dé Beeriṣeba. Ìdílé kọ̀ọ̀kan ní ọgbà àjàrà ati àwọn igi ọ̀pọ̀tọ́ tirẹ̀.