5. Àwọn tí ń gbé inú ayé ti ba ilé ayé jẹ́,nítorí pé wọ́n ti rú àwọn òfinwọ́n ti tàpá sí àwọn ìlànàwọ́n sì da majẹmu ayérayé.
6. Nítorí náà ègún ń pa ayé run lọ.Àwọn eniyan inú rẹ̀ ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn,iná ń jó àwọn olùgbé inú rẹ̀,eniyan díẹ̀ ni ó sì kù.
7. Ọtí waini ń ṣọ̀fọ̀.Igi èso àjàrà ń joró,gbogbo àwọn tí ń ṣe àríyá ti ń kẹ́dùn.
8. Ìró ìlù ayọ̀ ti dákẹ́,ariwo àwọn alárìíyá ti dópin.Àwọn tí ń tẹ dùùrù ti dáwọ́ dúró.
9. Wọn kò mu ọtí níbi tí wọ́n ti ń kọrin mọ́ọtí líle sì korò lẹ́nu àwọn tí ń mu ún.
10. Ìlú ìdàrúdàpọ̀ ti wó palẹ̀, ó ti dòfo,gbogbo ìlẹ̀kùn ilé ti tì, kò sì sí ẹni tí ó lè wọlé.
11. Ariwo ta lóde nítorí kò sí ọtí waini,oòrùn ayọ̀ ti wọ̀;ayọ̀ di àwátì ní ilẹ̀ náà.
12. Gbogbo ìlú ti di ahoro,wọ́n ti wó ẹnu ibodè ìlú wómúwómú.
13. Bẹ́ẹ̀ ní yóo rí ní ilẹ̀ ayé,láàrin àwọn orílẹ̀-èdèbí igi olifi tí a ti gbọn gbogbo èso rẹ̀ sílẹ̀,lẹ́yìn tí a ti kórè tán ninu ọgbà àjàrà.
14. Wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n ń kọrin ayọ̀,wọ́n ń yin OLUWA lógo láti ìhà ìwọ̀-oòrùn wá.
15. Nítorí náà ẹ fi ògo fún OLUWA ní ìhà ìlà-oòrùn;ẹ̀yin tí ń gbé etí òkun,ẹ fògo fún OLUWA Ọlọrun Israẹli.