7. Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé, nítorí wọ́n jẹ́ irú ọmọ Ábúrámù, gbogbo wọn nii ọmọ: “Ṣùgbọ́n, nínú Ísákì li a ó ti pe irú ọmọ rẹ̀.”
8. Èyí nì ni pé, kì í ṣe àwọn ọmọ nípa ti ara, ni ọmọ Ọlọ́run: ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìlérí ni a kà ní irú ọmọ.
9. Nítorí ọ̀rọ̀ ìlérí ni èyí: “Níwọ̀n àmọ́dún ni èmi yóò wá, Sárà yóò sì ní ọmọ ọkùnrin.”
10. Kì sì íṣe kìkì èyí; Ṣùgbọ́n nígbà tí Rèbékà pẹ̀lú lóyún fún ẹnìkan, fún Ísákì baba wa;
11. Nítorí nígbà tí kò tí ì bá àwọn ọmọ náà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tí ì ṣe rere tàbí búburú, (kí ìpinnu Ọlọ́run nípa ti ìyànfẹ́ kí ó lè dúró, kì í ṣe nípa ti iṣẹ́, bí kòse ti ẹni tí ńpeni;)
12. A ti sọ fún un pé, “Ẹ̀gbọ́n ni yóò máa sin àbúrò.”
13. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Jákọ́bù ni mo fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Ísáù ni mo kóríra.”
14. Njẹ́ àwa yóò ha ti wí? Àìsòdodo ha wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run bí? Kí a má ri!
15. Nítorí ó wí fún Mósè pé,“Èmi ó sàánú fún ẹni tí èmi yóò sàánú fún,èmi yóò sì se ìyọ́nú fún ẹni tí èmi yóò se ìyọ́nú fún.”
16. Ǹjẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ti ẹni tí ó fẹ́, kì í sì í se ti ẹni tí ń sáré, bí kò se ti Ọlọ́run tí ń sàánú.
17. Nítorí ìwé mímọ́ wí fún Fáráò pé, Nítorí èyí ni mo ṣe gbé ọ dìde, kí èmi kí ó le fi agbára mi hàn lára rẹ, kí a sì le máa ròyìn orúkọ mi ká gbogbo ayé.