1. Ǹjẹ́ àwa ó ha ti wí? Ṣé kí àwa ó jòkòó nínú ẹ̀ṣẹ̀, kí oore-ọ̀fẹ́ ba à lè máa pọ̀ sí i?
2. Kò lè rí bẹ́ẹ̀. Ṣé a tún le máa dẹ́sẹ̀ lẹ́yìn tí a ti fún wa ní ìṣẹ́gun lórí rẹ̀?
3. Nítorí a ti ṣẹ́gun agbára ẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí a di Kírísítẹ́nì tí a sì ṣe ìrìbọmi fún wa láti di apá kan Jésù Kírísítì nípasẹ̀ ikú rẹ̀, a borí agbára ìwà ẹ̀ṣẹ̀.
4. Ẹ ti gbé ògbólógbòó ara yín tí ń fẹ́ máa dẹ́sẹ̀ sin pẹ̀lú Kírísítì nígbà tí òun kú, àti nígbà tí Ọlọ́run Baba pẹ̀lú agbára ògo mú un padà sí ìyè, a sì fún yín ní ìyè tun tun rẹ̀ láti gbádùn rẹ̀, èyí ṣẹlẹ̀ nípa ìrìbọmi yín.
5. Nítorí pé ẹ̀yin ti di apá kan ara rẹ̀, àti pé ẹ kú pẹ̀lú rẹ̀, nígbà tí òun kú. Nísinsin yìí, ẹ ń pín ìyè tuntun rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì jí dìde gẹ́gẹ́ bí òun náà ti jí dìde.
6. Gbogbo èrò burúkú ọkàn yín ni a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀. Ẹ̀mí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sì ń fẹ́ láti máa dẹ́ṣẹ̀ nínú yín ni a ti sọ di aláìlera. Nítorí náà, ara yín tí ó ń fẹ́ láti máa dẹ́sẹ̀ kò sí lábẹ́ àkóso ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, kò sì ní láti jẹ́ ẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.
7. Nítorí pé nígbà tí ẹ ti di òkú fún ẹ̀ṣẹ̀, a ti gbà yín sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ gbogbo agbára ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ kò ní agbára lórí yín mọ́