29. Ṣùgbọ́n Jésù dá wọn lóhùn pé, “Àìmọ̀kan yín ni ó fa irú ìbéèrè báyìí. Nítorí ẹ̀yin kò mọ ìwé Mímọ́ àti agbára Ọlọ́run.
30. Nítorí ní àjíǹde kò ní sí ìgbéyàwó, a kò sì ní fi í fún ni ní ìyàwó. Gbogbo ènìyàn yóò sì dàbí àwọn ańgẹ́lì ní ọ̀run.
31. Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí, nípa ti àjíǹde òkú, tàbí ẹ̀yin kò mọ̀ pé Ọlọ́run ń bá yín sọ̀rọ̀ nígbà ti ó wí pé:
32. ‘Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísáákì, àti Ọlọ́run Jákọ́bù.’ Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run òkú, ṣùgbọ́n tí àwọn alààyè.”
33. Nígbà ti àwọn ènìyàn gbọ́ èyí ẹnu yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ.
34. Nígbà ti wọ́n sì gbọ́ pé ó ti pa àwọn Sadusí lẹ́nu mọ́, àwọn Farisí pé ara wọn jọ.
35. Ọ̀kan nínú wọn tí ṣe amòfin dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè yìí.
36. Ó wí pé, “Olùkọ́ èwo ni ó ga jùlọ nínú àwọn òfin?”
37. Jésù dáhùn pé, “ ‘Fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, gbogbo ẹ̀mí rẹ àti gbogbo inú rẹ.’
38. Èyí ni òfin àkọ́kọ́ àti èyí tí ó tóbi jùlọ.
39. Èkejì tí ó tún dàbí rẹ̀ ní pé, ‘Fẹ́ràn ọmọ ẹni kejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’
40. Lórí àwọn òfin méjèèjì yìí ni gbogbo òfin àti àwọn wòlíì rọ̀ mọ́.”