25. Bákan náà, bí ilé kan bá sì yapa sí ara rẹ, ilé náà kí yóò leè dúró.
26. Bí Èṣù bá sì díde sí ara rẹ, tí ó sì yapa, òun kí yóò le è dúró ṣùgbọ́n òpin rẹ̀ yóò dé.
27. Kò sí ẹni tí ó le wọ ilé ọkùnrin alágbára kan lọ, kí ó sì kó o ní erù lọ, bí kò se pé ó kọ́kọ́ de ọkùnrin alágbára náà ní okùn, nígbà náà ni yóò lè kó ẹrù ní ilé rẹ̀.
28. Lóòótọ́ ní mo wí fún yín, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ni a ó dárí jin àwọn ọmọ ènìyàn, àti gbogbo ọ̀rọ̀ òdì.
29. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí Ẹ̀mí Mímọ́, kì yóò rí ìdáríjì títí ayé, ṣùgbọ́n ó wà nínú èwù ẹ̀bi àìnípẹ̀kun.”
30. Òun sọ eléyìí fún wọn, nítorí tí wọ́n sọ pé, “Nípa agbára ẹ̀mí Èṣù ló ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.”
31. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ìyá àti àwọn arákùnrin rẹ̀ dé. Wọ́n dúró lóde, wọ́n sì rán ẹnìkan sí i pé kí ó pè é wá.
32. Àwọn ènìyàn tí wọ́n jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Ìyá àti àwọn arákùnrin rẹ wà lóde.”
33. Ṣùgbọ́n ó dá wọn lóhùn wí pé, “Ta ni í ṣe ìyá mi tàbí àwọn arákùnrin mi?”
34. Ó sì wò gbogbo àwọn tí ó jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀ yíká, ó sì wí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi:
35. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, òun ni arákùnrin mi àti arábìnrin mi àti ìyá mi.”