31. Olúwa sì wí pé, “Kí ni èmi ìbá fi àwọn ènìyàn ìran yìí wé? Kí ni wọ́n sì jọ?
32. Wọ́n dàbí àwọn ọmọ kékeré tí ó jókòó ní ibi ọjà, tí wọ́n sì ń kọ sí ara wọn, tí wọ́n sì ń wí pé“ ‘Àwa fọn fèrè fún yín,ẹ̀yin kò jó àwa sì ṣọ̀fọ̀ fún yín,ẹ̀yin kò sọkún!’
33. Nítorí Jòhánù Onítẹ̀bọmi wá, kò jẹ àkàrà, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu ọtí-wáìnì; ẹ̀yin sì wí pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù?’
34. Ọmọ ènìyàn dé, ó ń jẹ, ó sì ń mu; ẹ̀yin sì wí pé, ‘Wò ó, Ọ̀jẹun, àti ọ̀mùtí, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó òde àti àwọn “ẹlẹ́sẹ̀!” ’
35. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ rẹ̀ gbogbo dá a nipa ọgbọ́n tí ó lò.”
36. Farisí kan sì rọ̀ ọ́ kí ó wá bá òun jẹun, ó sì wọ ilé Farisí náà lọ ó sì jókòó láti jẹun.
37. Sì kíyèsí i, obìnrin kan wà ní ìlú náà, ẹni tí i ṣe ẹlẹ́sẹ̀, nígbà tí ó mọ̀ pé Jésù jókòó, ó ń jẹun ní ilé Farisí, ó mú ṣágo kekeré alabásítà òróró ìkunra wá,
38. Ó sì dúró tì í lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn, ó ń sọkún, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i fi omijé wẹ̀ ẹ́ ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ nù ún nù, ó sì ń fi ẹnu kò ó ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi òróró kùn wọ́n.
39. Nígbà tí Farisí tí ó pè é sì rí i, ó wí nínú ara rẹ̀ pé, “Ọkùnrin yìí ìbá ṣe wòlíì, ìbá mọ ẹni àti irú ẹni tí obìnrin yìí jẹ́ tí ń fi ọwọ́ kàn an, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”
40. Jésù sì dáhùn, ó wí fún un pé, “Símónì, Mo ní ohun kan sọ fún ọ.”Ó sì dáhùn pé, “Olùkọ́ máa wí.”
41. “Ayánilówó kan wà tí ó ní ajigbésè méjì: ọ̀kan jẹ ẹ́ ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta owó idẹ, èkejì sì jẹ ẹ́ ní àádọ́ta.