12. Jésù sì dahùn ó wí fún un pé, “A ti sọ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.’ ”
13. Nígbà tí Èṣù sì parí ìdánwò náà gbogbo, ó fi í sílẹ̀ lọ di sáà kan.
14. Jésù sì fi agbára Ẹ̀mí padà wá sí Gálílì: òkìkí rẹ̀ sì kàn kálẹ̀ ní gbogbo agbègbè tí ó yí i ká.
15. Ó sì ń kọ́ni nínú sínágọ́gù wọn; a ń yìn ín lógo láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ènìyàn wá.
16. Ó sì wá sí Násárẹ́tì, níbi tí a gbé ti tọ́ ọ dàgbà: bí ìṣe rẹ̀ ti rí, ó sì wọ inú sínágọ́gù lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ó sì dìde láti kàwé.
17. A sì fi ìwé wòlíì Àìsáyà fún un. Nígbà tí ó sì ṣí ìwé náà, ó rí ibi tí a gbé kọ ọ́ pé:
18. “Ẹ̀mí Olúwa ń bẹ lára mi,Nítorí tí ó fi àmì òróró yàn míláti wàásù ìhìnrere fún àwọn òtòsì.Ó ti rán mi wá láti wàásù ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn, àtiìtúnríran fún àwọn afọ́jú,àti láti jọ̀wọ́ àwọn tí a pa lára lọ́wọ́,
19. Láti kéde ọdún ojúrere Olúwa.”
20. Ó sì pa ìwé náà dé, ó fi í fún ìránṣẹ́, ó sì jókòó. Gbogbo àwọn tí ó ń bẹ nínú sínágọ́gù sì tẹjúmọ́ ọn.
21. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wí fún wọn pé, “Lónì-ín ìwé-Mímọ́ yìí ṣẹ ní etí yín.”
22. Gbogbo wọn sì jẹ́rìí rẹ̀, háà sì ṣe wọ́n sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ tí ń jáde ní ẹnu rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Ọmọ Jósẹ́fù kọ́ yìí?”
23. Jésù sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni ẹ̀yin ó pa òwé yìí sí mi pé, ‘Oníṣègùn, wo ara rẹ̀ sàn! Àwọn ohun tí àwá gbọ́ pé o ti ọwọ́ rẹ ṣe ní Kapanáúmù, ṣe é níhín yìí pẹ̀lú ní ilẹ̀ ara rẹ.’ ”