1. Pọ́ọ̀lù, Àpósítélì Jésù Kírísítì nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti Tìmótíù arákùnrin wa.
2. Sí àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn arákùnrin nínú Kírísítì tí wọ́n ń gbé ní ìlú Kólósè.Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún-un yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa.
3. Nígbàkúùgbà tí a bá ń gbàdúrà fún un yín ni a máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Baba Olúwa wa Jésù Kírísítì.
4. Nítorí a ti gbúròó ìgbàgbọ́ yín nínú Jésù Kírísítì, àti bí ẹ ti ṣe fẹ́ràn gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́.
5. Ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí ń ṣàn nínú ìrètí tí a gbé pamọ́ fún un yín ní ọ̀run èyí tí ẹ̀yin sì ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́ ìyìnrere náà.
6. tí ó ti wá sọ́dọ̀ yín. Káàkiri àgbáyé ni ìyìnrere yìí ń so èso tí ó sì ń dàgbà, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe láàrin yín láti ọjọ́ náà tí ẹ ti gbọ ọ́, tí ẹ sì ní ìmọ̀ oore-ọ̀fẹ́ nínú gbogbo òtítọ́ rẹ̀.
7. Ẹ̀yin ti kọ́ ọ lọ́dọ̀ Épáfúrà, ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wa olùfẹ́, ẹni tí ó jẹ́ olótìtọ́ ìránṣẹ́ Kírísítì ní ipò wa.
8. ẹni ti ó sọ fún wa nípa ìfẹ́ yín nínú ẹ̀mí.
9. Nítorí ìdí èyí, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ nípa yín, a kò yéé gbàdúrà fún yin, tí a sì ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fi ìmọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ kún yín nípaṣẹ̀ ọgbọ́n àti òye gbogbo tí ń ṣe ti Ẹ̀mí
10. Àwa sì ń gbàdúrà yìí kí ẹlẹ́gbẹ́ irú ìgbé ayé tó yẹ fún Olúwa kí ẹ sì máa wu ú ní gbogbo ọ̀nà, kí ẹ sì máa so èso rere gbogbo, kí ẹ sì máa dàgbà ninú ìmọ̀ Ọlọ́run.
11. pé kí a lè fi ipa gbogbo sọ yín di alágbára gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ àti ògo rẹ̀, kí ó lè ṣe é ṣe fún un yín láti máa tẹ̀ṣíwájú nínú sùúrù àti ìpamọ́ra pẹ̀lú ayọ̀.