Bánábà àti Ṣọ́ọ̀lù sì padà wá láti Jerúsálémù, nígbà ti wọ́n sì parí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn, wọn sì mú Jòhánù ẹni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Máàkù wá pẹ̀lú wọn.