34. Pétérù sì ya ẹnu rẹ, ó sì wí pé, “Nítòótọ́ mo wòye pé, Ọlọ́run kì í ṣe ojusajú ènìyàn.
35. Ṣùgbọ́n ni gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, ti ó sì ń ṣisẹ́ òdodo, ẹni ìtẹ́wọ́gbà ni lọ́dọ̀ rẹ̀.
36. Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run rán sí àwọn ọmọ Isírẹ́lì, nígbà tí a wàásù àlàáfíà nípa Jésù Kírísítì (Òun ni Olúwa ohun gbogbo)
37. Ẹ̀yin náà mọ ọ̀rọ̀ náà tí a kéde rẹ̀ yíká gbogbo Jùdíà, tí a bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ láti Gálílì, lẹ́yìn bamitíìsímù ti Jòhánù wàásù rẹ̀.
38. Àní gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run Ẹ̀mi Mímọ́ àti agbára; ẹni tí ó ń kiri ṣe oore, ó ń ṣe ìmúláradá gbogbo àwọn tí Èṣù sì ń pọ́n lójú; nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.