1. Kí ìfẹ́ ará o wà títí.
2. Ẹ má ṣe gbàgbé láti máa ṣe àléjò; nítorí pé nípa bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn ṣe àwọn áńgẹ́lì ní àlejò láìmọ̀.
3. Ẹ máa rántí àwọn òǹdè bí ẹni tí a dè pẹ̀lú wọn, àti àwọn tí a ń pọn lójú bí ẹ̀yin tikarayin pẹ̀lú tí ń bẹ nínú ara.