1. Ní ìgbà àtijọ́, Ọlọ́run bá àwọn baba ńlá wa sọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì ní ọ̀pọ̀ ìgbà àti ní onírúurú ọ̀nà,
2. ṣùgbọ́n ní ìgbà ìkẹyìn yìí Ọlọ́run ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ Jésù Kírísítì, ẹni tí ó fi ṣe ajogún ohun gbogbo, nípasẹ̀ ẹni tí ó dá gbogbo ayé yìí àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀:
3. Ọmọ tí í ṣe ìtànsán ògo Ọlọ́run àti àwòrán òun tìkálárarẹ̀, tí ó sì ń fi ọ̀rọ̀ agbára rẹ̀ mú ohun gbogbo dúró: Lẹ́yìn tí ó ti ṣe ìwẹ̀nù ẹ̀ṣẹ̀ wa tan, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ọlá-ńlá ní òkè.
4. Nítorí náà, ó sì ti fi bẹ́ẹ̀ di ẹni tí ó ga ní ipò ju ańgẹ́lì lọ, bí ó ti jogún orúkọ èyí tí ó tayọ̀ ti wọn.
5. Nítorí kò sí ọ̀kan nínú àwọn ańgẹ́lì tí Ọlọ́run fi ìgbà kan sọ fún pé:“Ìwọ ni ọmọ mi;lónì- ni mo bí ọ”?Àti pẹ̀lú pé;“Èmi yóò jẹ́ baba fún-un,Òun yóò sì jé ọmọ mi”?
6. Àti pẹ̀lú, nígbà tí Ọlọ́run rán àkọ́bí rẹ̀ wá si ayé wa yìí. Ó pàṣẹ pé,“Ẹ jẹ́ kí gbogbo àwọn ańgẹ́lì Ọlọ́run foríbalẹ̀ fún un.”
7. Àti nípa ti àwọn ańgẹ́lì, ó wí pé;“Ẹni tí ó dá àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ ní ẹ̀mi,àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ ìná.”
8. Ṣùgbọ́n ó sọ nípa tí Ọmọ rẹ̀ pé,“Ọlọ́run, ìjọba rẹ yóò wà láti ìran dé ìran,àti pé òdodo ni ọ̀pá tí ìwọ fi ń páṣẹ ìjọba rẹ.
9. Ìwọ fẹ́ òdodo,bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kórìíra iṣẹ́ búburú;nítorí èyí ni Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ ṣe fi òróró ayọ̀ yàn ọtí ó gbé ọ ju àwọn ẹgbẹ́ rẹ lọ.”