Báyìí ni Olúwa wí: “Mo yípadà sí Síónì èmi ó sì gbé àárin Jérúsálẹ́mù: Nígbà náà ni a ó sì pé Jérúsálẹ́mù ni ìlú ńlá otítọ́; àti òkè-ńlá Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ni a ó pè ní òkè-ńlá mímọ́.”