1. Gbọ́, Olúwa, kí o sì dà mí lóhùn,nítorí mo jẹ́ talákà àti aláìní.
2. Dáàbòbò ayé mi, nítorí a ti yà mí sọ́tọ̀ fún ọ:ìwọ ní Ọlọ́run mi,gbà ìránṣẹ́ Rẹ làtí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.
3. Ṣàánú fún mi, Olúwa,nítorí èmi ń pe ọ́ ní gbogbo ọjọ́.
4. Mú ayọ̀ wà fún ìránṣẹ́ Rẹ,nítorí ìwọ, Olúwa,ní mo gbé ọkan mí sókè sí.
5. Ìwọ ń daríjì, ìwọ sì dára, Olúwa,ìwọ sì ṣàánú fún gbogbo àwọn ti ń ké pè ọ́,
6. Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa;tẹ́tí sí ẹkún fún àánú.
7. Ní ọjọ́ ipọ́njú mi èmi yóò pe ọ́,nítorí ìwọ yóò dá mí lóhùn.