61. Ó rán àpótí ẹ̀rí, agbára Rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn,dídán ògo Rẹ̀ lọ sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá.
62. Ó fi àwọn ènìyàn Rẹ̀ lé idà lọ́wọ́,ó sì bínú sí àwọn ohun ìní Rẹ̀.
63. Iná run àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn,àwọn ọmọbìnrin wọn kò sì ní orin ìgbéyàwó:
64. A fi àlùfáà wọn fún idà,àwọn opó wọn kò sì le è sunkún.
65. Olúwa sì jí gẹ́gẹ́ bí ẹni ojú oorun,gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ti i jù kúrò nínú ìraníyè ọtí.
66. Ó kọlu àwọn ọta Rẹ̀ padà;ó fí wọn sínú ìtìjú ayérayé.