1. Ní Júdà ni a mọ Ọlọ́run;orúkọ Rẹ̀ sì lágbára ní Ísírẹ́lì
2. Àgọ́ Rẹ̀ wà ní Sálẹ́mù,ibùgbé Rẹ̀ ní Síónì.
3. Níbẹ̀ ní o ṣẹ́ ọfà,asà àti àwọn idà, ohun ìjà ogun. Sela
4. Iwọ ni ògo àti ọláJu òkè-ńlá íkogun wọ̀nyìí lọ.
5. Àwọn akíkanjú ọkùnrin A kó àwọn akíkanjú ogun ní ìkógunwọn sún oorun ìgbẹ̀yìn wọn;kò sí ọ̀kan nínú àwọn ajaguntó lè gbé ọwọ́ Rẹ̀ sókè.
6. Ní ìfìbú Rẹ, Ọlọ́run Jákọ́bù,àwọn ẹsin àti kẹ̀kẹ́ ogun sì dúbúlẹ̀ ṣíbẹ̀.
7. Ìwọ nìkan ni o yẹ kí a bẹ̀rù.Ta ló lé dúró níwájú Rẹ nígbà tí ìwọ bá ń bínú?
8. Ìwọ ń ṣe ìdàjọ́ láti ọ̀run,ilé ayé bẹ̀rù, ó sì dúró jẹ́ ẹ́: