13. Èmi ó wá sí tẹ́ḿpìlì Rẹ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísunkí n sì mú ẹ̀jẹ́ mi ṣẹ sí ọ
14. Ẹ̀jẹ́ ti ètè mi jẹ́, tí ẹnu mi sì sọnígbà tí mo wà nínú ìsòro.
15. Èmi o sun ẹbọ ọlọ́ràá sí ọàti ẹbọ ọ̀rá àgbò;èmi o rú akọ màlúù àti ewúrẹ́. Sela
16. Ẹ wá gbọ́ gbogbo ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Olúwa;ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tí ó ṣe fún mi.
17. Mo fi ẹnu mi kígbe sókè sí i:Ìyìn Rẹ̀ wà ní ẹnu mi.
18. Bí èmi bá gba ẹ̀ṣẹ̀ ní àyà mi, Olúwa kì yóò gbọ́ ohùn mi;
19. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbọ́ nítòótọ́o ti gbọ́ ohun mi nínú àdúrà.
20. Ìyìn ni fún Ọlọ́runẹni tí kò kọ àdúrà mitàbí mú ìfẹ́ Rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi!