6. Nígbà tí mo rántí Rẹ lórí ìbusùn mi;èmi ń ronú Rẹ títí iṣọ́ òru.
7. Nítorí ìwọ ni ìrànlọ́wọ́ mi,mo kọrin níbi òjijì-ìyẹ́ apá Rẹ.
8. Ọkàn mí fà sí ọ:ọwọ́ ọ̀tún Rẹ gbé mi ró.
9. Àwọn tí ó ń wá ọkàn mí ní a ó parun;wọn o sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìṣàlẹ̀ ilẹ̀ ayé.
10. Wọn ó ti ọwọ́ idà ṣubúwọn ó sì di jíjẹ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀.
11. Ṣùgbọ́n ọba yóò yọ̀ nínú Ọlọ́runẹni tí o fi orúkọ Ọlọ́run búra yóò sògoṣùgbọ́n ẹnu àwọn òpùrọ́ la ó pa mọ́.