1. Nínú Ọlọ́run nìkan ni ọkàn mi ti rí ìsinmi;ìgbàlà mi ti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ wá.
2. Òun nìkan ní àpáta mi àti ìgbàlà mi;oun ní ààbò mi, a kí yóò sí mi ní pò padà.
3. Ẹ̀yin ó ti máa rọ́lù ènìyàn kan pẹ́ tó?Gbogbo yín ni ó fẹ pa á,bí ògiri tí ó fẹ́ yẹ̀ àti bí ọgbà tí ń wó lọ?
4. Kìkì èró wọn ni láti bì ṣubúkúrò nínú ọlá Rẹ̀;inú wọn dùn sí irọ́.Wọn ń fi ẹnu wọn súre,ṣùgbọ́n wọ́n ń gégùn nínú ọkàn wọn. Sela
5. Nínú Ọlọ́run nìkan ni ìsinmí wà, ìwọ Ọlọ́run mi.Ìrètí mi wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ.
6. Òun nìkan ní àpáta àti ìgbàlà mi;Òun ni ààbò mi, a kí yóò sí mi nípò.