1. Gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi, Ọlọ́run;dáàbò bò mí kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ó dìde sí mi.
2. Gbà mí lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ búburúkí o sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tí ń pòǹgbẹ ẹ̀jẹ̀.
3. Wòó, bí wọ́n ṣe ba ní bùba dè mí!Àwọn alágbára ń gbìmọ̀ lòdì sí miKìí se nítorí ìrékọja mi tàbí ẹ̀ṣẹ̀ mí, Olúwa.
4. Èmí kò ṣe àìṣedédé kan, ṣíbẹ̀ wọ́n sáré,wọ́n ṣetán láti kọlù mi. Dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi,kí o sì wo àìlera mi.
5. Olúwa Ọlọ́run alágbára, Ọlọ́run Ísírẹ́lì,dìde fún ara Rẹ kí o sì bá àwọn orílẹ̀ èdè wí;Má ṣe ṣàánú fún àwọn olùrékọjá búburú nì. Sela
6. Wọ́n padà ní àṣálẹ́,wọ́n ń gbó bí àwọn ajá,wọ́n ń rìn yí ìlú náà káàkiri.
7. Kíyèsí ohun tí wọ́n tú jáde ní ẹnu:wọn ń tú idà jáde láti ètè wọn,wọn sì wí pé, “Ta ní ó le gbọ́ ọ̀rọ̀ wa?”
8. Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, yóò fi wọ́n rẹ́rin-ínÌwọ ó yọ ṣùtì sí gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè.
9. Ìwọ agbára mi, èmi ó máa kọrin ìyìn sí ọ;nítorí ìwọ Ọlọ́run ni ààbò mi,
10. Ọlọ́run àánú mi ni yóò ṣáájú mi.Ọlọ́run yóò sì jẹ́ kí èmi rí ìfẹ́ mi lára àwọn ọ̀tá mi.Yóò sì jẹ́ kí ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gún lórí àwọn ọ̀tá ìfẹ́ àwọn ọ̀ta mi.
11. Ṣùgbọ́n má ṣe pa wọ́n, Olúwa asà wa,kí àwọn ènìyàn mí má ba à gbàgbé.Nínú agbára Rẹ̀, jẹ́ kí wọ́n máa rìn kiri,kí ó sì Rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.
12. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ẹnu wọn,ni ọ̀rọ̀ ètè wọn,kí a mú wọn nínú ìgbéraga wọn.Nítorí ẹ̀gàn àti èké tí wọn ń sọ,
13. Pa wọn run nínú ìbínú,run wọ́n di ìgbà tí wọ́n kò ní sí mọ́.Nígbà náà ní yóò di mímọ̀ dé òpin ayépé Ọlọ́run jọba lórí Jákọ́bù. Sela