1. Nínú Rẹ̀, Olúwa ni mo ti rí ààbò;Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí;gbà mí nínú òdodo Rẹ.
2. Tẹ́ etí Rẹ sí mi,gbà mí kíákíá;jẹ́ àpáta ààbò mi,jẹ́ odi alágbára láti gbà mí.
3. Ìwọ pàápàá ni àpáta àti ààbò mi,nítorì orúkọ Rẹ máa ṣe ìtọ́ mi tọ́ mi kí o sì ṣe amọ̀nà mi.
4. Yọ mí jáde kúrò nínú àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ fún mi,nítorí ìwọ ni ìsádi mi.
5. Ní ọwọ́ Rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé;ìwọ ni ó tí rà mí padà, Olúwa, Ọlọ́run òtítọ́.
6. Èmi ti kórìíra àwọn ẹni tí ń fi yè sí òrìṣà tí kò níye lórí;ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.
7. Èmi yóò yọ̀, inú mi yóò dùn nínú ìfẹ́ ńlá Rẹ,nítorí ìwọ ti rí ìbìnújẹ́ miìwọ ti mọ̀ ọkàn mi nínú ìpọ́njú.