1. Ní ẹ̀bá odò Bábílónì, níbẹ̀ ní àwa gbé jókòóàwa sì sunkún nígbà tí àwa rántí Síónì.
2. Àwa fi dùùrù wa kọ́ sí orí igi wílóò,tí ó wà láàrin Rẹ̀.
3. Nítorí pé níbẹ̀ ní àwọntí ó kó wa ní ìgbékùn bèèrè orin lọ́wọ́ wá,àti àwọn tí ó ni wá lára bèèrè ìdárayá wí pé;ẹ kọ orin Síónì kan fún wa.
4. Àwa o ti ṣe kọ orin Olúwa ni ilẹ̀ àjèjì