9. Báwo ni àwọn èwe ènìyàn yóò ti ṣe pa ọ̀nà Rẹ̀ mọ́?Láti máa gbé ní ìbámu sí ọ̀rọ̀ Rẹ.
10. Èmi wá ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mimá ṣe jẹ́ kí èmi yàpa kúrò nínú àṣẹ̀ Rẹ.
11. Èmi ti pa ọ̀rọ̀ Rẹ mọ́ ní ọkàn mikí èmi má ba à ṣẹ̀ sí ọ
12. Ìyìn ni fún Olúwa;kọ́ mi ní àsẹ Rẹ.
13. Pẹ̀lú ètè mi èmi tún sírògbogbo òfin tí ó wá láti ẹnu Rẹ.
14. Èmi yọ̀ nínú títẹ̀lé òrin Rẹbí ènìyàn ṣe ń yọ̀ nínú ọlá ńlá.
15. Èmi ń ṣe àṣàrò nínú ìlànà Rẹèmi sì kíyèsí ọ̀nà Rẹ
16. Inú mi dùn sí àṣẹ Rẹ;èmi kì yóò gbàgbé ọ̀nà Rẹ.
17. Ṣe rere sí ìránṣẹ́ Rẹ, èmi yóò sì wà láàyè;èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Rẹ.
18. La ojú mi kí èmi lè ríran ríohun ìyanu tí ó wà nínú òfin Rẹ.