14. Ó mú kí koríko hù jáde fún àwọn ẹranko láti jẹàti àwọn ewébẹ fún ènìyàn láti lòkí ó le mú oúnjẹ jáde láti ilẹ̀ wá:
15. Ọtí wáìnì tí ó ń mú ọkàn ènìyàn yọ̀,òróró láti mú ojú Rẹ̀ tan,àti àkàrà láti ra ọkàn Rẹ̀ padà.
16. Àwọn igi Olúwa ni a bomi rin dáradára,Kédárì tí Lébánónì tí ó gbìn.
17. Níbẹ̀ ní àwọn ẹyẹ ṣe ìtẹ́ wọnbí ó se tí àkọ̀ ni, orí igi páìnì ni ilé Rẹ̀.
18. Àwọn òkè gíga ni ààbò fún àwọn ewúrẹ́ igbó;àti àwọn àlàpà jẹ ààbò fún àwọn ehoro.
19. Òsúpá jẹ àmì fún àkókòòòrùn sì mọ̀ ìgbà tí yóò wọ̀.
20. Ìwọ mú òkùnkùn wá, ó sì di òru,nínú èyí tí gbogbo ẹ̀ranko igbó ń rìn kiri.
21. Kìnnìún ń bú ramúramù fún ohun ọdẹ wọnwọ́n sì ń wá oúnjẹ wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
22. Òòrùn ràn, wọn sì kó ara wọn jọ,wọn padà lọ dùbúlẹ̀ sí ìhò wọn.