16. Ibojì, inú tí ó yàgàn,ilẹ̀, tí omi kì í tẹ́lọ́rùn láéláé,àti iná, tí kì í wí láéláé pé, ‘Ó tó!’
17. “Ojú tí ń fi baba ṣẹ̀fẹ̀,tí ó kẹ́gàn ìgbọràn sí ìyáẹyẹ àkálá ẹ̀bá odò ni yóò yọ ọ́,igún yóò mú un jẹ.
18. “Àwọn nǹkan mẹ́ta wà tí ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi,mẹ́rin tí kò yé mi:
19. Ipa idì ní òfuurufúipa ejò lórí àpátaipa ọkọ̀ ojú omi lójú agbami òkunàti ipa ọ̀nà ọkùnrin tí ó mú wúndíá lọ́wọ́.
20. “Èyí ni ọ̀nà alágbérè obìnrinó jẹun o sì nu ẹnu rẹ̀ó sì wí pé, N kò ṣe ohunkóhun tí kò tọ́.
21. “Lábẹ́ nǹkan mẹ́ta ni ile ayé ti ń wárìrìlábẹ́ ohun mẹ́rin ni kò ti lè mí fín ín.
22. Ìránṣẹ́ tí ó di Ọbaaláìgbọ́n tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ́
23. Obìnrin tí gbogbo ènìyàn kórìíra tí ó sì wá lọ́kọìránṣẹ́bìnrin tí ó gbọkọ mọ́ ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́.
24. “Àwọn ohun mẹ́rin ló kéré láyésíbẹ̀ wọ́n gbọ́n gidigidi;
25. Àwọn èrà jẹ́ ẹ̀dá tí ó ní agbára díẹ̀síbẹ̀ wọ́n kó oúnjẹ wọn pamọ́ ní àsìkò òjò
26. Ehoro jẹ́ ẹ̀dá tí kò ní agbára púpọ̀ṣíbẹ̀ wọ́n ń ṣe ilé wọn sí ibi ihò àpáta;
27. Eṣú kò ní ọbaṣíbẹ̀ wọ́n ń jáde lọ papọ̀ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́
28. a lè fi ọwọ́ mú aláǹgbáṣíbẹ̀ a ń rí i ní ààfin ọba.
29. “Àwọn ohun mẹ́ta ní n bẹ tí ń rìn rere,ohun mẹ́rin tí ń kọrí sí ibi rere,
30. Kìnnìún, alágbára láàrin ẹrankotí kì í sá fún ohunkóhun
31. Ẹsin tí a dì lẹ́gbẹ̀ẹ́; àti òbúkọ,àti ọba pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ láyìíká rẹ̀.
32. “Bí ìwọ bá ti hùwà aṣiwèrè nípa gbígbé ara rẹ ga,tàbí tí o bá ti gbèrò ibi,da ọwọ́ rẹ bo ẹnu rẹ!
33. Nítorí bí fífún omi ọmú tí í mú wàrà wátí fífún imú sì ń mú ẹ̀jẹ̀ jádebẹ́ẹ̀ ni rírú ìbínú sókè í mú ìjà wá.”