1. Yíyan orúkọ rere ṣàn ju púpọ̀ ọrọ̀ lọ,àti ojúrere dára ju fàdákà àti wúrà lọ.
2. Ọlọ́rọ̀ àti tálákà péjọ pọ̀: Olúwa ni ẹlẹ́dàá gbogbo wọn.
3. Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ti rí ibi tẹ́lẹ̀,ó ṣé ara rẹ̀ mọ́:ṣùgbọ́n àwọn òpè tẹ̀síwájú, a sì jẹ wọ́n níyà.
4. Èrè ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Olúwa ni ọrọ̀ ọlá, àti ìyè.
5. Ègún àti ìdẹkun ń bẹ ní ọ̀nà aláyídáyidà:ẹni tí ó bá pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yóò jìnnà sí wọn.